Matthew 17:9-13

9 aBí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.”

10 bÀwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?”

11Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. 12Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” 13Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni.

Copyright information for YorBMYO